Ọdún mẹ́sàn án rèé tí mo ti ń gbé pẹ̀lú àrun kògbóògùn, HIV kìí ṣe ìdájọ́ ikú – Chika Wonder

📌 Diğer 📰 Nigeria 🕐 3 saat önce
Ọdún mẹ́sàn án rèé tí mo ti ń gbé pẹ̀lú àrun kògbóògùn, HIV kìí ṣe ìdájọ́ ikú – Chika Wonder

Ọrọ ti Chika Ekezie ti ọpọ mọ si Chika Wonder sọ ree lasiko to ba BBC sọrọ lori irinajo rẹ pẹlu arun naa.

"Ti mo ba le maa ba arun HIV gbe, ẹnikẹni le ba arun naa gbe. Arun HIV kii ṣe idajọ iku."

Ọrọ ti Chika Ekezie ti ọpọ mọ si Chika Wonder sọ ree lasiko to ba BBC sọrọ lori irinajo rẹ pẹlu arun naa.

Lati ọdun mẹsan an ṣeyin ni Chika ti n gbe pẹlu arun naa to si ti n ṣe ilanilọyẹ nipa rẹ.

O ni "Ọdun mẹsan an niyi ti mo ti n ba arun HIV gbe amọ fun ọdun meje akọkọ ni mi o fi lo oogun mi nitori mo ṣi n ṣe ninu ọkan mi pe mi o ni arun naa. Eyii jẹ ọkan lara awọn idi ti mo fi n sọrọ nipa rẹ bayii.

"Lọpọ igba ni arun ọhun maa n da awọn eeyan laamu nipa oju ti wọn fi n wo o yatọ si ipo ilera ẹni to ni arun naa.

"Mo wa ṣakiyesi pe kii ṣe ara mi nikan ni mo n sọrọ soke fun, ṣugbọn mo n sọrọ soke fun ẹgbẹlẹgbẹ ọmọ Naijiria ti wọn n gbe pẹlu arun HIV pẹlu. Idi ree ti mo fi n sọrọ nipa rẹ.

"Ọpọlọpọ eeyan lo n gbe pẹlu arun HIV amọ ti wọn ko le sọrọ soke nipa ipo ti wọn wa, eyii ko si ṣẹyin idẹyẹsi awọn eeyan si wọn."

Chika ṣalaye fun BBC pe lati igba ti oun ti n sọrọ arun HIV lawọn eeyan ti n ṣe idẹyẹsi oun.

O ni "Lati igba ti mo ti sọ pe mo ni arun HIV lawọn ọrẹ mi ko ti ṣe bii ọrẹ si mi mọ.

"O ṣelẹ si mi nile ijọsin, ile ijọsin mi ṣe idẹyẹsi mi, mo ti lọ sibi ti wọn ti n gẹ irun ri pẹlu ẹrọ igẹrun ara mi, wọn kọ lati gẹ irun fun mi nibẹ.

"Ni nkan bii ọsẹ meji ṣeyin, mo lọ sile itura, wọn fi gilaasi wọn fun gbogbo awọn to wa nibẹ ni ẹlẹrindodo ayafi emi nikan ti wọn fi ife ti eeyan n lo lẹẹkanṣoṣo fun ni ẹlẹrindodo."

Chika ni oun ti fi oju opo oun wa ololufẹ fun awọn to n wa ololufẹ, koda awọn kan ti oun gbe fun ara wọn ti fẹ ara sile bayii gẹgẹ bii tọkọtaya.

Nipa ọrọ ife ti ara rẹ, o ni lẹyin ti oun kede pe oun ni arun naa, o ti ṣoro fun oun lati ni ololufẹ, koda, oun ko ri ẹni to n gbe pẹlu arun naa fẹ pẹlu.

O pari ọrọ rẹ pẹlu arọwa si awọn to ni arun naa ki wọn ye maa gbe arun ọhun sori nitori wọn ki n kọ ọ siwaju ori eeyan pe wọn ni arun HIV.

📌 Kaynak

Bu özet Nigeria kaynağından otomatik derlenmiştir. Tamamı için orijinal habere gidin.

Orijinal haberi oku →
📱
News AI World — Mobil uygulama
Bu haberleri 45 dilde, anlık çeviriyle cebinde. Erken erişim için Gmail adresini bırak.
← Tüm haberlere dön