Àdó olóró agbésùnmọ̀mí ṣekúpa ọlọ́pàá mẹ́ta

📌 Diğer 📰 Nigeria 🕐 2 saat önce
Àdó olóró agbésùnmọ̀mí ṣekúpa ọlọ́pàá mẹ́ta

Orukọ awọn agbofinro to padanu ẹmi naa bi ijọba ipinlẹ Zamfara ṣe kede ni: Abdulrazak Musa Hassan, Auwal Ahmad ati Murtala Musa.

Ko din ni ọlọpaa mẹta to padanu ẹmi wọn lọjọ Aje ọsẹ yii, nigba ti awọn agbesunmọmi kan kẹ́ ado oloro silẹ fun ọkọ wọn nipinlẹ Zamfara.

Orukọ awọn agbofinro to padanu ẹmi naa bi ijọba ipinlẹ Zamfara ṣe kede ni: Abdulrazak Musa Hassan, Auwal Ahmad ati Murtala Musa.

Ipo 'Superintendent of Police' (SP) ni Oloogbe Abdulrazak Musa Hassan wa nigba aye rẹ ki ọlọjọ too de, nigba ti Auwal Ahmad ati Murtala Musa wa nipo 'Inspector'

Gẹgẹ bi ijọba ipinlẹ Zamfara ṣe fidi ẹ mulẹ, awọn ọlọpaa mẹta naa wa lati ẹka to n ri si ado oloro nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Zamfara.

Alaye ijọba ipinlẹ Zamfara lori iṣẹlẹ yii ni pe awọn agbesunmọmi kẹ́ ado oloro silẹ loju ọna Bagega, eyi to wa nijọba ibilẹ Anka, niluu Zamfara.

Awọn agbofinro ko mọ eyi, ẹnu iṣẹ oojọ wọn ni wọn wa ti wọn fi gbe ọkọ wọn kọja nibi ti awọn agbesunmọmi naa ti kẹ ado oloro si.

Iroyin sọ pe bi wọn ṣe kọja lori ado oloro naa lai mọ lo bugbamu, eyi to si fa iku awọn agbofinro mẹta naa.

Ni ibanikẹdun awọn akọni to sun loju ija yii, Akọwe ijọba ipinlẹ Zamfara, Abubakar Mohammad Nakwada, lewaju ikọ awọn eekan ninu ijọba ipinlẹ naa lọ sibi ti wọn ti ṣeto isinku wọn.

Ọga ọlọpaa pata ni Naijiria, Olatunji Disu, wa lara awọn eeyan nla lẹnu iṣẹ ọlọpaa to ba wọn kirun si awọn oloogbe naa lara lasiku ti wọn n sin wọn.

Akọwe ijọba Zamfara ninu ọrọ rẹ, sọ pe iṣẹlẹ yii ko ni i mu kijọba tẹriba fun awọn bandiiti, bi ko ṣe pe awọn yoo fi kun igbiyanju awọn si i ni.

Bakan naa ni gomina ipinlẹ Zamfara, Dauda Lawal ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi awọn agbofinro mẹta naa, kọmandi ọlọpaa ilu naa ati gbogbo ajọ ọlọpaa Naijiria pata.

Ẹ o ranti pe ipinlẹ Zamfara jẹ ọkan lara awon ibi tawọn agbesunmọmi ti n ṣọṣẹ lorilẹede yii, to si fi foju wina ikọlu ọlọkan-o-jọkan ṣaaju asiko yii.

📌 Kaynak

Bu haber XML kaynağından derlenmiştir. Tamamı için orijinal habere gidin.

Orijinal haberi oku →
📱
News AI World — Mobil uygulama
Bu haberleri 45 dilde, anlık çeviriyle cebinde. Erken erişim için Gmail adresini bırak.
← Tüm haberlere dön