Wo bí Ọlọ́pàá ṣe ká ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbọn, ọta ìbọn, aṣọ ẹgbẹ́ òṣèlú Accord àti ọkọ̀ lákàtà afurasí adigunjalè, Surii Ilupeju ní Ibadan

📌 Diğer 📰 Nigeria 🕐 5 saat önce
Wo bí Ọlọ́pàá ṣe ká ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbọn, ọta ìbọn, aṣọ ẹgbẹ́ òṣèlú Accord àti ọkọ̀ lákàtà afurasí adigunjalè, Surii Ilupeju ní Ibadan

Ibọn marun un, ọta ibọn mọkanlelọgbọn, ọkọ bọọsi mẹfa pẹlu ọkọ mẹrin miran atawọn ọkada wa lara ohun ti wọ̀n ba ni ikawọ afurasi naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti kede pe oniruru ohun ija oloro, alupupu, ọkọ akero ati aṣọ ẹgbẹ oṣelu Accord loun ba lakata afurasi adigunjale, Surajudeen Babatunde Adio, ti inagijẹ rẹ n jẹ "Surii Ilupeju".

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Ayanlade Olayinka lo fidi ọrọ ọhun mulẹ ninu atẹjade kan.

Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun 2026 yii ni ọlọpaa sọ pe oun mu Surii Ilupeju pẹlu afurasi mẹrin mii lori ẹsun idigunjale ati nini ohun ija oloro ni ikawọ wọn.

Ayanlade sọ pe asiko iwadii awọn lawọn ṣawari oniruru ohun ija oloro ni akata afurasi ọhun.

Yatọ si awọn ibọn yii, ọlọpaa ni ohun tun ri awọn ọkọ lakata rẹ bii

Yatọ si awọn ọkọ yii,ọlọpaa ni oun tun ri awọn alupu nibẹ bii alupupu Suzuki Inazuma Power Bike kan, to fi mọ awọn alupupu Honda ti ko ṣiṣẹ.

Awọn nnkan mii ti wọn tun ri lakata rẹ gẹgẹ bii ọrọ ọlọpaa ni ọpọlọpọ aṣọ ati fila ipolongo ibo fun ẹgbẹ oṣelu Accord.

Ti ẹ ko ba gbagbe, inu ẹgbẹ oṣelu Accord yii ni Oriyomi Hamzat ti fẹ dije du ipo gomina ipinlẹ Oyo.

Amọ ṣa, Oriyomi ti sọ ni gbangba pe oun ko ni ibaṣepọ kankan pẹlu afurasi adigunle naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ awọn to ni awọn dukia naa ati ibaṣẹpọ wọn pẹlu awọn adigunjale to wọn mu.

📌 Kaynak

Bu haber XML kaynağından derlenmiştir. Tamamı için orijinal habere gidin.

Orijinal haberi oku →
📱
News AI World — Mobil uygulama
Bu haberleri 45 dilde, anlık çeviriyle cebinde. Erken erişim için Gmail adresini bırak.
← Tüm haberlere dön