Inú ìbànújẹ ọkàn ni mo wà torí àwọn ọmọdé wà ninu awọn èèyàn tawon janduku agbébọn ji gbe, bẹẹ, o ti le ni oṣu kan bayii- Makinde
Makinde sọrọ yii lasiko ti alẹ́nulọ́rọ̀ ori ayélujára, Very Dark Man, at'awọn ọdọ mii n ṣèwọ́de niluu Ibadan lati pe fún ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wọn ji gbe ọhun.
Makinde ni inu ìbànújẹ ọkàn loun wa torí àwọn ọmọde wa ninu awon eeyan tawon janduku agbébọn ji gbe eyi to ti le ni oṣu kan bayii.
Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti ṣalaye idi tawon akẹkọọ àtàwọn olùkọ́ táwọn janduku agbébọn agbébọn ji gbe ni Esinele ati Yawota l'Ogbomoso ko fi tii gbòmìnira lọwọ àwọn ajinigbe.
Makinde sọrọ yii lasiko ti alẹ́nulọ́rọ̀ ori ayélujára, Very Dark Man, at'awọn ọdọ mii n ṣèwọ́de niluu Ibadan lati pe fún ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wọn ji gbe ọhun.
Níbẹ ni gomina tun ti ṣeleri wi pe oun yóò ri wi pe gbogbo awọn to wa lakata awon ajinigbe lo pada wale ni alaafia.
O ti le ni oṣu kan bayii tí wọ́n ti wa ninu igbo pẹlu awọn janduku agbébọn," Makinde lo sọ bẹẹ.
Gomina ipinle Oyo loun ko ni le so ibi táwọn ẹṣọ eleto aabo ba iṣẹ dé tori bi ọrọ iṣẹlẹ naa ṣe ri.
Amọ, gomina fi da awon araalu loju pe gbogbo awọn akẹẹkọ ti wọn ji gbe ni yoo pada sile laipẹ.
Makinde ni igba akọkọ niyi ni Naijiria táwọn agbébọn yoo ji àwọn ọjẹwẹwẹ akẹkọọ tí ko tíì le da ṣe nnkan kan funra won gbe lọ.
Gomina ipinle Oyo ni oun ko fẹ padanu ẹnikẹni ninu awọn ti wọn ji gbe.
Makinde ni iru iṣẹlẹ yii ko ni waye mọ n'ipinle Oyo, leyin tawon ẹṣọ eleto aabo ba ti doola awon to wa lakata awon ajinigbe.
Oni, ọjọ Aje, ọjọ Kẹẹdogun, oṣu Kẹfa lo pe oṣu kan geerege tawọn agbebọn kọlu ile ẹkọ LA School ati Community High School, Ahoro-Esinele, niluu Ogbomoso, ipinlẹ Oyo.
Nibi ikọlu naa ni awọn agbebọn yii pa olukọ kan, ji olukọ pẹlu awọn akẹkọọ ti apapọ iye wọn jẹ mẹrindinlaaadọta (46).
Gẹgẹ bi atẹjade ti Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Ayanlade Olayinka, fi sita lọjọ Ẹti, ọjọ Kẹẹdogun, oṣu Karun-un ti wọn ji awọn eeyan naa gbe lọ, o ni nnkan bii aago mẹjọ si mẹsan-an aarọ ni awọn ajinigbe yawọ ile ẹkọ naa lati ṣọṣẹ.
Awọn akẹkọọ n ṣeto orin kikọ ti won maa n ṣe lori ila lasiko ti awọn agbebọn naa de ti wọn ṣina ibọn bolẹ, wọn gbe ọga agba ile ẹkọ naa, Abilekọ Rachael Alamu pẹlu awon akẹkọọ ti ẹnikẹni ko mọ iye wọn lọ.
Lẹyin ọjọ meji ti ikọlu naa waye ni awọn ajinigbe naa gbe fidio kan jade nibi ti olukọ agba ile ẹkọ naa Esinele, Rachael Alamu ti n rawọ ẹbẹ sijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Oyo lati ma jẹ ẹ kawọn ku sakata awọn ajinigbe naa.
Arabinrin Alamu sọ ninu fidio naa pe oun ṣe fidio yii lati beere fun iranwọ lọwọ gbogbo eeyan, bẹrẹ lati ọdọ ijọba apapọ Naijiria, Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo, ajọ awọn ọmọlẹyin Kristi, CAN ati gbogbo eeyan lati tete wa bi awọn ṣe maa kuro ni ahamọ awọn ajinigbe naa.
"Mo fẹ ki ẹ bawa yanju ọrọ yii ni itubi inubi ki a maa baa ku sibi.''
Nigba to tun di ọjọ Kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun un yii, to jẹ ayajọ ọjọ awọn ọmọde lagba
📌 Kaynak
Bu haber XML kaynağından derlenmiştir. Tamamı için orijinal habere gidin.
Orijinal haberi oku →