Géńdé mẹ́wàá wọlé tọ̀ wá, wọ́n ṣá ọkọ mi ládàá lórí àti ọrùn ká lè kúrò nílùú- Àjòjì tó ń gbé South Africa

📌 Diğer 📰 Nigeria 🕐 4 saat önce
Géńdé mẹ́wàá wọlé tọ̀ wá, wọ́n ṣá ọkọ mi ládàá lórí àti ọrùn ká lè kúrò nílùú- Àjòjì tó ń gbé South Africa

Orilẹede naa ti di ibi ibẹru fun ọpọ eeyan to n gbe nibẹ lai jẹ pe ọmọ oniluu ni wọn.

Bi awọn ọmọ orilẹede South Africa ṣe n le awon ajoji to n gbe lorilẹede wọn kuro ko duro rara, niṣe lo n peleke si i.

Orilẹede naa ti di ibi ibẹru fun ọpọ eeyan to n gbe nibẹ lai jẹ pe ọmọ oniluu ni wọn.

Bakan naa lo si ti di pe awọn ti wọn niwee igbeluu paapaa ṣugbọn ti wọn ki I ṣe ọmọ ilu naa ti n foju wina ifiyajẹni.

Obinrin ọmọ orilẹede Malawi kan, Esnat Joseph, ẹni ọdun mẹrindinlogoji ( 36), ṣalaye fun BBC nipa bo ṣe n gbe niluu naa pẹlu ipayinkeke.

"Niṣe ni mo sa kuro nile ti a n gbe lati maa lọ gbe ni agọ awọn ti ko nibi ti wọn yoo gbe, nibi ti ajoji to to ẹgbẹrun meje wa.

"Awọn eeyan yẹn wa sile mi, wọn sọ fun wa pe awọn ko fẹ ka duro nibi, wọn ni ka ko ẹru wa ka pada si orilẹede wa."

"Gende mẹwaa ni wọn, wọn mu ada dani ati ẹgba dani. Wọn ṣa ọkọ mi ladaa lori, wọn di ọrun rẹ mu un bii pe wọn fẹ ge e, Ọlọrun ni ko jẹ ko ku. Amọ o ṣi wa nile iwosan bayii."

Esnat to bi ibẹta ti ọjọ ori wọn ko ti i ju ọdun kan lọ, sọ fun BBC pe oun de South Africa lọdun mẹta sẹyin.

O ni oun sọ iwe irinna oun nu pẹlu awon iwe miran nigba ti ole ja oun.

Erongba rẹ bo ṣe wi ni lati pada si Malawi pẹlu ọkan lara awọn ọkọ ti ijọba ilu naa gbe kalẹ.

Ẹka to n ri si ọrọ abẹle ni South Africa ti kede pe oun ti n di iwe idanimọ awọn eeyan kan ti wọn jẹ ọmọ oniluu pa.

Awọn alaṣẹ naa sọ pe awọn ṣe bẹẹ nitori awọn kan ti n gbabọde ninu wọn.

Wọn ni wọn yoo ni lati lọ fi ara wọn han fawọn alaṣẹ fun idanimọ tootọ.

Bakan naa ni wọn ni awọn ti n wadii awọn iwe kan boya wọn jẹ gidi abi bẹẹ kọ.

Koda, wọn fi kun un pe bawọn ti ọrọ idanimọ yii kan ko ba mura, o le di ohun ti wọn yoo gbẹsẹ le e patapata.

Eredi ti wọn fi di awọn idanimọ naa pa bi wọn ṣe wi, ni pe awọn fura si wọn pe wọn fi wọn lu jibiti fawọn eeyan ajoji.

Ni bayii, ọgbọnjọ oṣu Kẹfa yii ni wọn fun awọn ajoji lati kuro ni South Africa.

Bi ọjọ naa si ṣe n sunmọle ni ipaya n ba awọn ajoji to wa lati awọn ilu bii Malawi, Naijiria, Ghana, Mozambique, Zimbabwe ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii ni iṣi akọkọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria to n koju ipayinkeke yii de sorilẹede yii. Bẹẹ naa si ni awọn orilẹede ilẹ Africa mi-in ṣe n ko awọn eeyan wọn pada sile.

📌 Kaynak

Bu haber XML kaynağından derlenmiştir. Tamamı için orijinal habere gidin.

Orijinal haberi oku →
📱
News AI World — Mobil uygulama
Bu haberleri 45 dilde, anlık çeviriyle cebinde. Erken erişim için Gmail adresini bırak.
← Tüm haberlere dön