Ilé ẹjọ́ ní mínísítà epo rọ̀bì ní Naijiria tẹ́lẹ̀ Alison-Madueke kò jẹ̀bi ẹsùn rìbá gbígbà tí wọ́n fi kàn án

📌 Diğer 📰 Nigeria 🕐 5 saat önce
Ilé ẹjọ́ ní mínísítà epo rọ̀bì ní Naijiria tẹ́lẹ̀ Alison-Madueke kò jẹ̀bi ẹsùn rìbá gbígbà tí wọ́n fi kàn án

Alison-Madueke ẹni ọdun marundinlaadọrin di ipo minisita epo rọbi mu laarin ọdun 2010 si 2015.

Ile ẹjọ kan lorilẹede UK ti dajọ pe Minisita fun epo rọbi tẹlẹ ni Naijiria, Diezani Alison-Madueke, ko jẹbi ẹsun riba gbigba ti wọn fi kan an.

Idajọ yii jẹ ijakulẹ fun ajọ NCA to n gbogun ti iwa ibajẹ eyi to bẹrẹ iwadii Alison-Madueke lati ọdun 2013 ti o si fọwọ ofin mu un niluu London lọdun 2015.

Alison-Madueke ẹni ọdun marundinlaadọrin di ipo minisita epo rọbi mu laarin ọdun 2010 si 2015.

Oun si ni adari obinrin akọkọ ajọ OPEC to n ri si ọrọ epo rọbi lagbaaye.

Alison-Madueke ko jẹbi ọkankan ninu ẹsun onikoko marun un ti wọn fi kan an.

Awọn ogbontarigi oniṣowo epo rọbi fẹsun riba gbigba kan an to fi mọ gbigba nnkan mere mere ti owo rẹ to £2m lati ọwọ Harrods.

Amọ, lati igba ti igbẹjọ naa ti bẹrẹ loṣu Kinni lawọn agbẹjọro Alison-Madueke ti sọ pe minisita tẹlẹ naa ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti wọn fi kan an.

Awọn agbẹjọro minisita tẹlẹri naa tun sọ pe ọpọ iwe ẹri to le tọka si i wi pe Alison-Madueke ko mọwọ mẹsẹ nipa ẹsun ti wọn fi kan an lo di awati ni Naijiria.

Bakan naa ni wọn tun sọ pe bi igbẹjọ naa ko ṣe tete bẹrẹ ko dara, o si tun tumọ si pe eto idajọ Ilẹ Gẹẹsi ko muna doko mọ.

Ile ẹjọ Southwark Crown tun dajọ pe ibatan Alison-Madueke, Doye Agama, ti wọn fẹsun kan pe o gbimọ pọ lati gba riba naa ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Ọjọ kẹfa oṣu Kejila ọdun 1960 ni wọn bi Diezani Alison-Madueke si ilu Port Harcourt, nipinlẹ Rivers.

Oun ni obinrin akọkọ to jẹ aarẹ ajọ OPEC to n ri sọrọ epo rọbi lagbaaye.

Ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Keje ọdun 2007 ni Alison-Madueke di minisita fun igbokegbodo ọkọ.

Lọdun 2008 ni Alison-Madueke di minisita ohun alumọni inu ilẹ ati irin.

Loṣu Kẹrin ọdun 2010 ni o di minisita obinrin akọkọ fun epo rọbi ni Naijiria, ki o to di aarẹ ajọ OPEC lọdun 2014.

📌 Kaynak

Bu haber XML kaynağından derlenmiştir. Tamamı için orijinal habere gidin.

Orijinal haberi oku →
📱
News AI World — Mobil uygulama
Bu haberleri 45 dilde, anlık çeviriyle cebinde. Erken erişim için Gmail adresini bırak.
← Tüm haberlere dön