Kí ni àyájọ́ 7-7 túmọ̀ sí àti itú tàwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn le pa láti sàmì àyájọ́ náà

📌 Diğer 📰 Nigeria 🕐 4 saat önce
Kí ni àyájọ́ 7-7 túmọ̀ sí àti itú tàwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn le pa láti sàmì àyájọ́ náà

Atẹjade ti ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ati Osun fisita lori ayajọ ẹgbẹ okunkun 7-7, ti wa n sin awọn araalu ni gbẹrẹ ipakọ pe ki wọn fura nipa ọsẹ tawọn ẹlẹgbẹ okunkun naa le se.okunkun naa le se.

Gbogbo ọjọ keje, oṣu Keje ọdọọdun ni awọn ẹlẹgbẹ okunkun ya sọtọ lati sami idasilẹ ẹgbẹ Neo-Black Movement of Africa, eyi ti a tun mọ si Black axe.

Ṣugbọn ṣa, lọdọọdun, isami ayajọ idasilẹ naa ki i ba alaafia de fun araalu, afi ipayinkeke.

Yoruba si ni ifura ni oogun agba, bẹẹ si ni ifura naa ni agba oogun.

Idi ree tawọn ileeṣẹ ọlọpaa lawọn ipinlẹ kan ni Naijiria ṣe kilọ nipa iru itu buruku ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun jakejado orilẹede yii le pa, ni ayajọ oni ti i ṣe ọjọ keje, oṣu Keje ọdun.

Atẹjade ti ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ati Osun fisita ti wa n sin awọn araalu ni gbẹrẹ ipakọ pe ki wọn fura nipa ọsẹ tawọn ẹlẹgbẹ okunkun naa le se.

Bakan naa, ni awọn ileesẹ ọlọpaa yii tun kede awọn igbesẹ ti wọn fẹ gbe lati sọ ete ipaniyan ati dida alaafia ilu ru, ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa fẹ gbe di asan.

Ni ti ayajọ ọjọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun, wọnyi ni ohun ti ileeṣẹ ọlọpaa kilọ pe o ṣeeṣe kawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa danwo:

Bo tilẹ jẹ pe igbagbọ ọpọ eeyan ni pe ọjọ keje, oṣu Keje ni wọn fi n sami idasilẹ ẹgbẹ Neo Black Movement of Africa (NBM), ko sibi ti wọn kọ ọ si loju opo ayelujara wọn pe ayajọ idasilẹ awọn niyẹn.

Ṣugbọn gbogbo 7-7 ni ikilọ maa n waye, koda, awọn ẹlẹgbẹ okunkun mi-in gan-an yoo maa dunkooko mawọn eeyan lati bọwọ fun ọjọ naa.

Ohun ti ẹgbẹ naa sọ pe awọn wa fun ni lati gbe iran eeyan dudu ga kaakiri agbaye.

Gẹgẹ bi awọn akọsilẹ kan ṣe wi, awọn akẹkọọ mẹsan-an kan ti wọn jẹ ọmọ Naijiria lo da ẹgbẹ "Neo-Black Movement of Africa" (NBM) silẹ laaarin 1970, lati tako ẹlẹyamẹya kaakiri agbaye.

Ṣugbọn lati bii ọdun meloo kan sẹyin bayii ti awọn ọlọpaa lati US, UK ati Canada ti n tọpinpin ẹgbẹ naa ni wọn ti n sọ pe ẹgbẹ okunkun ni.

Wọn fẹsun kan wọn pe wọn n lọwọ si magomago, gbigbe oogun oloro ati tita eeyan si oko ẹru .

Ni Naijiria, 7-7 ki I lọ lai si ikilọ lati ọdọ awọn agbofinro, nitori ikọlu awọn ẹlẹgbẹ okunkun si ni.

Orukọ Black ace ti wọn si tun mọ wọn si, jẹyọ ninu aworan idanimọ wọn ti i ṣe aake ti wọn ni awọn fi n ge imunisin ni.

Lati dena rogbodiyan lo le ti ọwọ awọn ẹlẹgbẹ okunkun wa lonii, ileeṣẹ ọlọpaa kede pe oun ti ṣepade pẹlu awọn olotẹẹli, awọn onibudo igbafẹ, ilee faaji ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Wọn kilọ pe kawọn onileeṣẹ yii mọ iru awọn eeyan ti wọn yoo gba lalejo ni 7-7, ko ma di pe awọn ẹlẹgiri yoo lo ibẹ fun iṣẹ ibi ati jagidijagan.

Ileeṣẹ ọlọpaa kilọ pe kawọn obi, alagbatọ, olori agbegbe ati awọn alẹnulọrọ gbogbo, ba awọn ọmọ wọn sọrọ nibi ti wọn ti n gbọ.

Wọn ni ki wọn jẹ kawọn ọmọ mọ ewu to wa ninu lilọwọ si jagidijagan, ati ijiya ti ofin la kalẹ fun un.

Bakan naa ni wọn rọ araalu lati foju ṣọri, ki wọn si tete fi akojọpọ

📌 Kaynak

Bu haber XML kaynağından derlenmiştir. Tamamı için orijinal habere gidin.

Orijinal haberi oku →
📱
News AI World — Mobil uygulama
Bu haberleri 45 dilde, anlık çeviriyle cebinde. Erken erişim için Gmail adresini bırak.
← Tüm haberlere dön