Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo gbẹ̀mí afurasí ajínigbé méjì lójú ọ́nà Owo lẹ́yìn tí wọ́n ṣíná ìbọn fúnra wọn

📌 Diğer 📰 Nigeria 🕐 46 dk önce
Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo gbẹ̀mí afurasí ajínigbé méjì lójú ọ́nà Owo lẹ́yìn tí wọ́n ṣíná ìbọn fúnra wọn

Ọlọpaa ni awọn ri ibọn ilewọ agbelẹrọ meji, ọta ibọn, awọn iboju meji, ẹrọ ilewọ ati kaadi ATM lakata wọn lẹyin ikọlu naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti gbẹmi afurasi ajinigbe meji ni Ilu-Abo to wa loju ọna maroṣe Akure siluu Owo lẹyin ti awọn afurasi ajinigbe n aadoju ibọn kọ ọlọpaa.

Ọlọpaa ni awọn ri ibọn ilewọ agbelẹrọ meji, ọta ibọn, awọn iboju meji, ẹrọ ilewọ ati kaadi ATM lakata wọn lẹyin ikọlu naa.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa, DSP Abayomi Jimoh fi lede, o ni nnkan bii aago mẹta abọ idaji ni iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti wọn ke pe ọlọpaa pe awọn afurasi naa n ṣọṣẹ nileeṣe Olaiya Block Industry, to wa lẹgbẹ ile ẹkọ girama Ilu-Abo High School.

Jimo sọ pe iwadii awọn fi han pe gende ọkunrin meje lo y abo ileeṣẹ Olaiya Block Industry, ti wọn si sọ pe awọn fẹ ri ẹni to ni ileeṣẹ naa.

O ni "Ni kete ti a gbọ ni awọn akọṣẹmọṣẹ ọlọpaa tẹkọ leti lọ sibẹ ti awọn afurasi naa si ṣina ibọn bọle, ọlọpaa da ibọn naa pada ti iro ibọn si n dun lakọlakọ.

"Ninu ikọlu naa ni ẹmi ajinigbe meji ti bọ ti awọn akẹgbẹ yoku si na papa bora sinu igbo to wa nitosi lẹyin ti wọn fara gbọta ibọn.

"Ẹwẹ, a ri ibọn agbelẹrọ ilewọ meji, ọta ibọn, awọn iboju meji, ẹrọ ilewọ ati kaadi ATM lara awọn afurasi meji naa lẹyin ikọlu ọhun."

Jimoh sọ siwaju si pe wọn ti ko oku awọn afurasi meji naa lọ sile iwosan ijọba to wa niuluu Akure, wọn si ti taare ọrọ naa si ẹka Antikidnapping to n ṣewadii ẹsun ijinigbe.

O fi kun pe iṣẹ n lọ lọwọ lati ṣawari awọn afurasi to kan lu igbo ki awọn naa le foju wina ofin bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.

Agbẹnusọ ọlọpaa naa wa rọ awọn araalu, paapaa awọn to n ṣiṣẹ iṣegun ki wọn sin awọn ni gbẹrẹ ipakọ ti ẹnikẹni to ba wa sọdọ wọn fun itọju ọgbẹ ọta ibọn.

Ẹwẹ, o ni awọn ko ni ṣiwọ iṣẹ titi di iṣẹlẹ ijinigbe yoo fi di ohun igbagbe nipinlẹ Ondo.

O pari ọrọ rẹ pẹlu ọrọ idupẹ fun awọn eeyan ipinlẹ ọhun fun ifọwọsowọpọ wọn lati sọ ijinigbe atawọn iwa ọdaran mii di ohun igbagbe nipinlẹ Ondo.

📌 Kaynak

Bu haber XML kaynağından derlenmiştir. Tamamı için orijinal habere gidin.

Orijinal haberi oku →
📱
News AI World — Mobil uygulama
Bu haberleri 45 dilde, anlık çeviriyle cebinde. Erken erişim için Gmail adresini bırak.
← Tüm haberlere dön