Ṣé lóòótọ́ ni ọmọbìnrin akẹ́kọ̀ọ́ kan ti kú sígbèkùn ajínigbé nínú àwọn tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso? Àlàyé rèé

📌 Diğer 📰 BBC Yoruba 🕐 7 saat önce
Ṣé lóòótọ́ ni ọmọbìnrin akẹ́kọ̀ọ́ kan ti kú sígbèkùn ajínigbé nínú àwọn tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso? Àlàyé rèé

Iroyin naa lo tubọ mu ibanujẹ ati ikayasoke wa, bẹẹ ni o da omi tutu si ọkan ọpọ ọmọ Naijiria.

Lẹnu lọọlọ yii ni fọto ọmọbinrin kekere kan to wọṣọ ile ẹkọ bẹrẹ si I kari ayelujara, pẹlu iroyin kan ti won fi n gbe e lẹṣẹ, pe ọkan lara awon akekọọ ti ajinigbe ko wọgbo lọ l'Ogbomoso ni, ati pe ọmọ naa ti ku sigbekun pẹlu.

Gẹgẹ bi ìṣe ọpọ eeyan lori ayelujara, kia ni won ti n pin aworan omode naa ka, ti iroyin iku rẹ si gbode kan.

Koda, wọn fi kun un pe iya ọmọdebinrin naa ti gba kamu, wọn ni niṣe lo sọ pe oun mọ pe ọmọ oun le ma pada wale, nitori ara rẹ ko le nigba ti won gbe e wọgbo lọ.

Iroyin naa lo tubọ mu ibanujẹ ati ikayasoke wa, bẹẹ ni o da omi tutu si ọkan ọpọ ọmọ Naijiria.

Amọ ṣe otitọ ni pe ọmọdebinrin naa ti ku latari inira to koju nigbo ajinigbe ti wọn wa?

Lati fi okodoro ọrọ yii mulẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo lati ọwọ Alukoro wọn, DSP Ayanlade Olayinka, fi atẹjade kan sita lọjọ Ẹti, ninu eyi to ti sọ pe:

"Kọmandi ọlọpaa Oyo n sọ gbangba pe irọ, iroyin aṣinilọna ati ti èké ni, ko si ni otitọ kan ninu rẹ bo ti wu ko mọ."

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ṣalaye pe oun tabi ileeṣẹ ẹṣọ alaabo kankan to n gbiyanju nipa bawon eeyan to wa nigbekun yoo ṣe jade ko kede iroyin ofege bẹẹ.

Atẹjade naa sọ pe awon eeyan to wa nidii ibajẹ, to fẹ da wahala silẹ ti won si fẹẹ ko araalu lọkan soke lo n gbe iroyin yii kiri.

"Ileeṣẹ ọlọpaa ipinle Oyo fi n da araalu loju, pe awọn ẹṣọ alaabo ṣi n ṣiṣẹ nilana akọṣẹmọṣẹ gidi, eyi ti ko ni I ṣakoba fun igbiyanju lati gba awon to wa nigbekun silẹ, ti ko si ni I ko awọn ẹbi tọrọ kan si ipayinkeke tabi ṣi araalu lọna."

Fun idi eyi, Kọmandi ọlọpaa ipinlẹ Oyo n kilọ gidi fun kaluku, awọn oniroyin ayelujara, sọrọsọrọ lori ayelujara ati ẹka iroyin gbogbo lati ma ṣe gbe iroyin to le da omi alaafia ilu ru tabi ko araalu laya soke, iwakiwa ti a ko fi aaye gba ni."

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni awon ajinigbe yabo ile ẹkọ mẹta niluu Ogbomoso.

Ahoro Esinele, Yawota ati Alausa ni wọn ti ṣiṣẹ ibi naa, ti wọn pa olukọ kan lasiko ikọlu, ko akẹkọọ mẹtadinlogoji, olukọ meje wọgbo lọ.

Lẹyin ọjọ diẹ ti wọn ko wọn lọ ni awọn ajinigbe naa fi aworan ibi ti wọn ti bẹ ori olukọ kan, Micheal Ojedokun, sori ayelujara.

Latigba naa ni igbesẹ ti n waye lati ri awon to wa nigbekun naa gba kalẹ, eyi to ti pe ọsẹ mẹta bayii.

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti tako aba lati bawọn agbebọn ti wọn ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe l'Ogbomoso dunaadura.

Adari ile, Họnarebu Adebo Ogundoyin, lo fi idi ọrọ yii mulẹ lasiko ti ile jiroro lori ọrọ naa.

Ninu fidio kan to ṣafihan ijokoo ile igbimọ aṣofin Oyo ni adari ile ti sọ pe ijọba ko ni sanwo fawọn agbesunmọmi lati fawọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe lominira.

📌 Kaynak

Bu özet BBC Yoruba kaynağından otomatik derlenmiştir. Tamamı için orijinal habere gidin.

Orijinal haberi oku →
← Tüm haberlere dön