Saheed Osupa, gbajúmọ̀ akọrin fuji ti pariwo síta lórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso; ohun tó sọ rèé
Lọjọ kẹẹdogun oṣu Karun un to kọja lawọn janduku agbebọn yabo ile ẹkọ girama Esinele ati ile ẹkọ alakọbẹrẹ ijọ Onitẹbọmi Baptist Nursery and Primary School ni Yawota nibi ti wọn ti ji eeyan to le logoji gbe.
Gbajugbajaa akọrin Fuji, Saheed Osupa, ti kepe ijọba lati doola awọn akẹkọọ ati olukọ ti wọn ji gbe ni Esinele ati Yawota nijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso ni kiakia.
Lọjọ kẹẹdogun oṣu Karun un to kọja lawọn janduku agbebọn yabo ile ẹkọ girama Esinele ati ile ẹkọ alakọbẹrẹ ijọ Onitẹbọmi Baptist Nursery and Primary School ni Yawota nibi ti wọn ti ji eeyan to le logoji gbe.
Ọrọ ijinigbe naa ti di nnkan ti ọpọ eeyan n sọ nipa rẹ bayii papaa julọ lẹyin tawọn agbebọn naa ṣe afihan fidio ọkan lara awọn olukọ ti wọn ji gbe, Michael Oyedoku, eyi ti wọn ti bẹ ori rẹ.
Fidio ọga ile ẹkọ girama Esinele, Arabinrin Rachael Alamu, nibi to ti n bẹ ijọba atawọn lajọlajọ lati doola awọn to wa lakata ajinigbe naa tun ti jẹ kawọn eeyan tun maa sọ nipa iṣẹlẹ naa.
Arabinrin Alamu rọ ijoba wi pe ki won ma lo ipa tori awọn agbebọn naa ti fẹ pa ẹlomiran ninu awọn.
Ninu ọrọ rẹ, Osupa fi orin kepe ijọba wi pe ki wọn sa gbogbo apa wọn lati doola awọn akẹkọọ naa.
''Ijọba gbọdọ doola awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe ni kiakia, tori awọn obi wọn ko jẹ anfaani orilẹede yii,'' Oṣupa lo sọ bẹẹ.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti sọ pe ọrọ gidi ni gbajumọ olorin naa sọ, ti awọn naa si n pe fun itusilẹ awọn ọmọ ile ẹkọ atawọn olukọ wọn ti wọn wa lakata ajinigbe ọhun.
Awọn oluwọde to n pe fun itusilẹ awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe l'Ogbomoso ti ja geeti olu ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun to wa l'Abeokuta wọle.
Awọn eeyan naa ti wọn ko ara wọn lati fi aidunnu wọn han si bawọn eeyan naa ṣe wa ni akata awọn ajinigbe lati ọjọ kẹẹdogun oṣu Karun un ti kọja, bẹnu ẹtẹ lu bi ijọba ko ṣe tii ri wọn doola.
Titi pa ni geeti olu ileeṣẹ ijọba naa nigba ti wọn de ibẹ, eyi lo si jẹ ki wọn fi ipa ṣi geeti naa wọle lati le fi aidunnu wọn han si ijọba.
Ọpọ eeyan lo ti pin fidio ifẹhonuhan naa kaakiri ori itakun ayelujara.
Ni ipinlẹ Osun, ẹgbẹ awọn olukọ ẹka ti ipinlẹ naa dara pọ mọ iwọde to n lọ lati pe fun itusilẹ awọn akẹkọọ atawọn olukọ to wa ni akata awọn ajinigbe.
Ifẹhonuhan naa lo waye ni ilu Osogbo to si gbera sọ ni deede agogo mẹwaa ku iṣẹju mẹsan an.
Iwọde naa bẹrẹ lati agbegbe Ataoja ti wọn si gbe e wọ inu ọfiisi ijọba ni Abere.
Pẹlu oju kikoro ati omije loju ni awọn olukọ naa fi ṣe iwọde naa ti orin aro si n jade lẹnu wọn bi wọn ṣe n ṣe iwọde naa lọ.
Awọn oluwọde naa kepe ijọba Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ati ijọba gomina Ademola Adeleke lati pasẹ aabo to peye fun olukọ ati akẹkọ paapa fun gbogbo ara ilu.
''Bi ko ba si aabo fun wa, a ti ṣe tan lati bẹrẹ iyanselodi.
A fun ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Ọyọ ni ọjọ meje pere lati gba awọn akẹkọọ ati olukọ to wa ni akata awọn ajinigbe ni ipinlẹ Ọyọ silẹ.''
📌 Kaynak
Bu özet BBC Yoruba kaynağından otomatik derlenmiştir. Tamamı için orijinal habere gidin.
Orijinal haberi oku →