Ìjàmbá ọkọ̀ ló fa ikú òṣèré tíátà, 'Janmole' - Mr Latin

📌 Diğer 📰 BBC Yoruba 🕐 3 gün önce
Ìjàmbá ọkọ̀ ló fa ikú òṣèré tíátà, 'Janmole' - Mr Latin

Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere TAMPAN, Ọgbẹni Bolaji Amusan, tawọn eeyan mọ si Mr Latin lo fi iroyin iku naa lede loju opo Instagram rẹ.

Ọfọ nla mii tun ṣẹ lagbo ere tiata Yoruba, iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe oṣere mii, Adesina Okiki Oshin, ti ọpọ eeyan mọ si Janmole ti jade laye.

Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere TAMPAN, Ọgbẹni Bolaji Amusan, tawọn eeyan mọ si Mr Latin lo fi iroyin iku naa lede loju opo Instagram rẹ.

Aarẹ TAMPAN gbadura pe ki Eleduwa tẹ ẹ si afẹfẹ rere, ki Ọlọrun si tu ẹbi, ọrẹ atawọn akẹgbẹ rẹ ninu.

Mr Latin ni ẹgbẹ ko ni gbagbe ipa ti Janmole ko ninu ẹgbẹ nigba aye rẹ.

Iku Janmole jẹ iyalẹnu fun ọpọ ololufẹ rẹ papaa julọ pẹlu bi ori ṣe ko o yọ ninu ninu ijamba ọkọ kan ni nnkan bi ọdun kan sẹyin.

Inu ọpọ eeyan lo dun nigba to gbadun tan lẹyin ijamba ọkọ naa.

Iku Janmole tun jẹ nnkan to ba ọpọ eeyan lọkan jẹ lẹyin ti agba oṣere Fesogboye Oyewole ṣẹṣẹ ku laipẹ yii.

📌 Kaynak

Bu özet BBC Yoruba kaynağından otomatik derlenmiştir. Tamamı için orijinal habere gidin.

Orijinal haberi oku →
← Tüm haberlere dön