Taa ni Balogun Kuku, bàbá olówó tó mú ẹ̀sìn Islam wọ ilẹ̀ Ijebu, tó tún bẹ̀rẹ̀ ọdún Ojude Ọba?
Itan igbe aye Balogun Bello Kuku, ẹni to mu Islam wọ ilẹ Ijẹbu, to si tun bẹrẹ ayẹyẹ ọdun Ojude Oba to di gbaju-gbaja ni Ijebu Ode.
Odu ni Balogun Kuku nilẹ Ijẹbu, ti ọpọ eeyan si mọ ile awodamiẹnu to kọ silu Ijẹbu Ode, eyi ti ọpọ awọn elere tiata ma n lo fun ere wọn lasiko yii.
Eyi lo gbe BBC Yoruba de ilu Ijebu Ode lati foju gan ni ile Balogun Kuku, ka si mọ nipa itan igbesi aye rẹ, paapaa bo se da ayẹyẹ Ojude Oba silẹ nilu Ijebu Ode.
BBC Yoruba ba Asiwaju fun idile Balogun Bello Kuku nilu Ijebu Ode, to tun jẹ Ọgbeni Ọja tilẹ Ijebu, Olorogun Ọmọwe Sunny Folorunso Kuku, sọrọ nipa itan aye akọni jagunjagun yii.
Olorogun Kuku, ti i se iran kẹfa si akọni jagunjagun naa ni, apetan orukọ baba nla idile awọn naa ni Bello Odueyungbo ( Ifa ko lọ sinu igbo) Bórogún.
Oriki lasan ni Kuku jẹ fun baba naa eyi to pada di orukọ rẹ ti gbogbo idile rẹ n jẹ.
Orukọ naa wa lati ara gbolohun "iya Kú, ọmọ Kù". Apapọ rẹ lo di Kuku.
"Mama to bi baba nla wa yii ku laarin ọjọ mẹta to bi, mama mama rẹ lo tọ ọ dagba, to si kọ Kuku ni ọna okoowo.
Kuku n se okoowo karakata, to si n ta nnkan ijagun nilẹ Yoruba. Eyi lo sọ ọ di olowo tabua, milọnia, ko to pe ọmọ ọdun mẹẹdogun.
Bi ogun ba wa nilẹ Yoruba, ẹni ti Kuku ba se atilẹyin fun pẹlu nnkan ijagun, ni yoo bori ogun naa, to si ni orisirisi ọta ibọn to maa n ta fun ẹni kọọkan.
Ogbeni Ọja salaye siwaju si pe, idi katakara eroja ijagun yii ni Balogun Kuku ti di jagunjagun nitori o ni ibọn ati ọmọ ogun pupọ ti yoo daabo bo awọn to ba kọwọrin pẹlu rẹ.
"Bi ogun ba de, Balogun Kuku lo ma siwaju ogun fun ilẹ Ijẹbu, o lowo lọwọ, onisowo ni, to si maa n doju kọ awọn adigunjale.
Oun si ni Awujalẹ maa n lọ lati jagun bii ogun Kiriji, ohun si ni Olori awọn Parakoyi onisowo to di ẹgbẹ awọn onisowo Chambers of Commerce loni yii."
Nigba ti Oloye Sunny Kuku n salaye ipa ti Balogun Kuku ko ninu awọn ẹsin igbalode ti igbagbọ ati Musulumi nilẹ Ijebu, ọrọ pọ ninu iwe kọbọ.
Lara ohun to pa ni lẹrin ni itan bi Balogun Kuku se gba lati di ọmọlẹyin Kristi amọ ti akude wọ igbesẹ rẹ naa.
Gẹgẹ bi Sunny Kuku ti wi, awọn Krisitẹni lo wọ ilu Ijẹbu Ode wa, ti wọn si wa waasu fun Balogun Kuku lati di ọmọlẹyin Kristi tori o ni ero pupọ.
"Balogun Kuku lo ni ilu, o si fẹran ẹsin Krisitẹni naa , to si gba lati di ọmọlẹyin Kristi amọ Pasitọ sọ fun pe yoo mu ọkan soso ninu iyawo marundinlaadọrin to ni.
Kuku wa sọ fun Pasitọ pe ko wa lọjọ kan lati wa se iribọmi fun oun, ti yoo si tun ba oun mu iyawo kansoso ninu awọn iyawo oun, ti yoo sẹku sinu ile.
Kuku pe awọn iyawo rẹ, to si salaye isẹlẹ yii fun wọn, awọn iyawo duro de Pasitọ, bo si se de, wọn ko pankẹrẹ bo Pasitọ, ti wọn si lu jade kuro ninu ile wọn."
Ogbeni Oja ni idi ree ti Balogun Kuku ko se di ọmọlẹyin Kristi mọ, se o kuku mọ
📌 Kaynak
Bu özet BBC Yoruba kaynağından otomatik derlenmiştir. Tamamı için orijinal habere gidin.
Orijinal haberi oku →