Àlàyé rèé nípa fọ́tò tó ṣàfihàn Ààrẹ Tinubu tó kúnlẹ̀ níta gbangba, tí pásítọ̀ gbọ́wọ́ lé e lórí

🤖 Yapay Zekâ 📰 BBC Yoruba 🕐 29.05.2026
Àlàyé rèé nípa fọ́tò tó ṣàfihàn Ààrẹ Tinubu tó kúnlẹ̀ níta gbangba, tí pásítọ̀ gbọ́wọ́ lé e lórí

Ninu ọsẹ yii naa ni ọrọ fọnran ohun ti wọn fi AI gbe jade bọ sori ayelujara, nibi ti wọn ti fi ohùn ẹnu Tinubu sọ awọn ọrọ to n tako araalu, to si le da rugudu silẹ.

Ẹni to n pe ọ ko duro, o ni o n gbọ agbọya ni ohun to n ṣẹlẹ pẹlu aworan ati ohùn ẹnu Aarẹ Bola Tinubu ti awọn eeyan fi n da orisirisi ara lori ayelujara lasiko yii, ojumọ kan, iroyin kan ni.

Tuntun to jade bayii ni fọto kan to ṣafihan Tinubu, nibi to ti kunlẹ siwaju pasitọ, tiyẹn si gbọwọ le e lori.

Ninu fọto naa, bi Aarẹ ṣe kunlẹ siwaju pasitọ naa lo tun tẹwọ adura bii ẹni to n ṣe adura nilana ẹsin Islam.

Tẹ o ba gbagbe, ninu ọsẹ yii naa ni ọrọ fọnran ohun ti wọn fi AI gbe jade bọ sori ayelujara, nibi ti wọn ti fi ohùn ẹnu Tinubu sọ awọn ọrọ to n tako araalu, to si le da rugudu silẹ.

Fọto to ṣafihan ibi ti Tinubu ti kunlẹ siwaju pasitọ naa ko jade lasan, fọnran ohun kan naa gbe e lẹsẹ.

Fọnran naa lo n ṣalaye pe Aarẹ lọ sibi isọji ita gbangba, o si kunlẹ siwaju pasitọ to gbọwọ le e lori.

Ninu fọto naa ni ẹni to n ṣalaye ọrọ ti sọ pe Aarẹ Tinubu fi Aso Rock silẹ, o si gbera lọ siluu Eko nileejọsin kan to darukọ.

Ẹni naa sọ pe ọpọ ọkọ lo tẹle e lẹyin bi iṣe rẹ, nigba ti wọn si debẹ ni Aarẹ sọkalẹ to si lọ ba pasitọ Ebika Obi to jẹ olori ile ijọsin naa.

Ẹni naa tẹsiwaju pe Aarẹ fi ohun irẹlẹ sọrọ pe oun wa sibi ijọsin naa bii ẹni to nilo Oluwa, nitori awọn ọmọ Naijiria ko gbagbọ ninu oun mọ, ati pe ipohunrere ẹkun pọ ni Naijiria lasiko yii.

O fi kun un pe Aarẹ beere ayipada lati oke wa nipasẹ pasitọ naa to gbagbọ pe o le ba a ṣẹgun iṣoro Naijiria.

O fi kun un pe nigba ti Aarẹ ko tiju, to le kunlẹ lojude lati beere ayipada lọwọ ẹni to mọna, awọn eeyan yoo ri iyatọ ti yoo ba orilẹede Naijiria.

Bi fọto ati fidio yii ṣe jade sori ayelujara ni ileeṣẹ Aarẹ naa ti tete fesi lori rẹ.

Ẹka to n ri si lilo imọ ayelujara nileeṣẹ Aarẹ lo tete fi atẹjade sita pe:

"A tun ti gbọ nipa awọn to n gbiyanju lati lo ọrọ ẹsin fi tako oṣelu.

"Lanaa, fidio ti wọn gbe fọnran ohun irọ le lori, ti wọn fi n sọ aburu nipa aarẹ ni wọn gbe jade. Sọrọsọrọ kan ni wọn lo fi ṣe eyi.

"Lonii, ayederu fidio ti wọn to pọ, ti wọn so olori ẹsin kan mọ ni wọn gbe jade lati le jẹ kawọn Musulumi binu si Aarẹ."

Ileeṣẹ Aarẹ sọ pe ko jẹ ijọloju pe awọn nnkan bayii n jade lọpọ lasiko yii, nitori awon to wa nidii rẹ n wa ọna ti wọn yoo fi da oju otitọ delẹ ni.

Wọn fi kun un pe ko sohun to jọ fọto ati fidio yii, ayederu ti wọn fi imọ ẹrọ gbe kalẹ ni.

Ninu atẹjade naa ni wọn ti ṣalaye, pe Aarẹ Tinubu ko fi ẹsin rẹ bo ri, Musulumi ni, Kristẹni si ni iyawo rẹ.

Eyi ko di Tinubu lọwọ lati jẹ olori to ko awọn ẹsin yoku mọra bi wọn ṣe ṣalaye, o si nigbagbọ ninu alaafia, itẹsiwaju ati iṣọkan gbogbo ilu.

Gbigbe awọn nnkan bawọnyi jade ki i ṣe nitori igbagbọ tabi ifẹ ilu, ko si ki n ṣe oṣelu pẹlu

📌 Kaynak

Bu özet BBC Yoruba kaynağından otomatik derlenmiştir. Tamamı için orijinal habere gidin.

Orijinal haberi oku →
← Tüm haberlere dön